\
Home » RCCG Sunday School Manual » YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL Ẹ̀KỌ́ KẸẸ̀DỌ́GBỌ̀N: ỌJỌ́ KOKÀNDÍNLÓGÚN, OSU KEJI, ỌDÚN 2023

YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL Ẹ̀KỌ́ KẸẸ̀DỌ́GBỌ̀N: ỌJỌ́ KOKÀNDÍNLÓGÚN, OSU KEJI, ỌDÚN 2023

Support the Good work on this Blog

CLICK HERE TO SUPPORT US

God Bless you



Subscribe to Blog via Email

Enter your email address to subscribe to this blog and receive notifications of new posts by email.

Table of Contents

IWE ILE EKO OJO ISINMI TI OLUKO TI ODUN 2023
IWE ILE EKO OJO ISINMI TI OLUKO TI ODUN 2023

Support the Good work on this Blog

CLICK HERE TO SUPPORT US

God Bless you

Paycheap.ng

YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL

Ẹ̀KỌ́ KẸẸ̀DỌ́GBỌ̀N: ỌJỌ́ KOKÀNDÍNLÓGÚN, OSU KEJI, ỌDÚN 2023 –

AKORI: AGBÁRA YÍYÀN

À̀DÚRÀ ÌBẸ̀RẸ̀: Baba, kọ́mi láti lóye nípa agbára yíyàn kí n má bàá kọ lọ́nà ipá.
ÌMỌ̀ ÀTẸ̀HÌNWÁ: Kí olùkọ́ gba akẹ́kọ̀ọ́ kan láyè láti ṣe àtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́ ti ọ̀sẹ̀ tó kọjá.
(I) BÍBÉLÌ KÍKÀ: Gẹnẹsisi 13:8-13.
. Abramu si wi fun Loti pe, Emi bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki gbolohùn asọ̀ ki o wà lãrin temi tirẹ, ati lãrin awọn darandaran mi, ati awọn darandaran rẹ; nitori pe ará li awa iṣe.
9.Gbogbo ilẹ kọ́ eyi niwaju rẹ? emi bẹ̀ ọ, yà ara rẹ kuro lọdọ mi: bi iwọ ba pọ̀ si apa òsi, njẹ emi o pọ̀ si ọtún; tabi bi iwọ ba pọ̀ si apa ọtùn, njẹ emi o pọ̀ si òsi.
10. Loti si gboju rẹ̀ si oke, o si wò gbogbo àgbegbe Jordani, pe o li omi nibi gbogbo, ki OLUWA ki o to pa Sodomu on Gomorra run, bi ọgbà OLUWA, bi ilẹ Egipti, bi iwọ ti mbọ̀wa si Soari.
11. Nigbana ni Loti yàn gbogbo àgbegbe Jordani fun ara rẹ̀; Loti si nrìn lọ si ìha ìla-õrùn: bẹ̃ni nwọn yà ara wọn, ekini kuro lọdọ ekeji. 12. Abramu si joko ni ilẹ Kenaani, Loti si joko ni ilu àgbegbe nì, o si pagọ́ rẹ̀ titi de Sodomu.
13. Ṣugbọn awọn ọkunrin Sodomu ṣe enia buburu, ati ẹlẹṣẹ gidigidi niwaju OLUWA.
(II) ẸSẸ̀ ÀKỌ́SÓRÍ: ”Ẹ jẹ́ kí á se ìdájọ́ yàn fún ara wa; ẹ jẹ́ kí á mọ̀ ohun tí ó dára láarín wa” Jobu 34:4.
(III) ÌFÁÀRÁ: Ní kùkurú, yíyàn nííes pẹ̀lú mímú láàárín nǹkan tí ó ṣeéṣe kí ó pọ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Agbára yíyàn jẹ́ níní ìtara tí ó la láti ṣe ìpinnu kan láarín onírúurú àṣàyàn tí ó wà nílẹ̀.
Nígbà tí ó jẹ́ pé ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn ni pé ẹ̀dá tí ó ó ń yàn ni ènìyàn jẹ́, ìwé mímọ́ fihàn gbangba pé Ọlọ́run ti fún ènìyàn ní agbára láti yân (Jos.24:15). Ṣùgbọ́n, àtúnbọ̀tán ohunkóhun tí a bá yàn yóò wà pẹ̀lú wa bóyá rere tàbí búburú ni. Ó wá kù sọ́wọ́ wa láti yan èyí tí ó dára ti yóò sì padà sọ bí ayé wá yóò ṣe rí.
ÀKỌSÍLẸ̀ OLÙKỌ́
(I) ÌLÉPA Ẹ̀KỌ́: Láti kọ́ nípa agbára yíyàn.
(II) ÈRÒǸGBÀ Ẹ̀KỌ́: Nípaṣẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, àwon akẹ́kọ̀ọ́ yóò lè:
a. Sọ ìtumọ̀ “Yíyan”. b. Ṣàlàyé ohun tí agbára yíyàn túmọ̀ sí. d. Dárúkọ onírúurú yíyàn tí ó wọ́pọ̀ àti àtúnbọ̀tán wọn. e. Dárúkọ àwọn ohun tí ó lè nípá lórí yíyàn.
(III) ÈTÒ KÍKỌ́NI: Láti lè ṣe àwọn èróńgbà òkè yìí, kí olùkọ́ :
a. Fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ka ẹsẹ̀ àkọ́sórí, bíbélì kíkà, dá sí ìjíròrò, ṣe iṣẹ́ ṣíṣe ti kíláásì àti isẹ́ àṣetiléwá wọn. b. Fààyè sílẹ̀ fún igbákejì olùkọ́ láti mójútó kíláásì, kí ó sì buwọ́lùwé wíwásí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti iṣẹ́ àṣetiléwá. d. Kọ́ ìlànà ẹ̀kọ́ méjèèjì, ṣe àkópọ̀, àkótán, ìgbéléwọ̀n ẹ̀kọ́ àti fún akẹ́kọ̀ọ́ ní iṣẹ́ àṣetiléwá.
(IV) ÀTÚNYẸ̀WÒ BÍBÉLÌ KÍKÀ: Gẹnẹsisi 13:8-13.
Ìwé mímọ́ ṣe àkọsílẹ̀ bí Abram ṣe yàn (Ìpinnu) láti má bàá gba ìjà lórí ilẹ̀ láàyè kí ó ba ìbáṣepọ̀ tí ó dánmọ́rán tó wà láarín òun àti Lọti, jẹ́ ó bá Lọ́tì sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó fi wá ìyànjú láti dáwọ́ ìjà tí ó ti fẹ́ máa gbilẹ̀ síi láarín àwọn darandaran wọn.
A. Abram wí fún Lọri pé:
i. —–ẹsẹ 8a.
ii. ———ẹsẹ 8b.
iii. ——–ẹsẹ 9a.
iv. ——–ẹsẹ 9b.
v. ——–ẹsẹ 9d.
vi. ——–ẹsẹ 9e.
B. Lọ́tì gbójúsókè, ó sì wó ———ẹsẹ 10a.
i. Pé ó dára—–ẹsẹ 10b.
ii. Bí ọgbà —–ẹsẹ 10d.
iii. Nígbà náà——–ẹsẹ 11a.
D. Abramu jókòó ——ẹsẹ 12a.
ii. Lọti jókòó—–ẹsẹ 12b.
E. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Sódómù —–ẹsẹ 13.
(V) ỌGBỌ́N ÌKỌ́NI: Ọgbọ́n ìkọ́ni ọlọ́rọ̀ geere.
(VI) LÍLÒ ÀKÓKÒ: Kí olùkọ́ pín àkokò ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí sórí ìlànà ẹ̀kọ́ mejèèjì.
2. ÌLÀNÀ Ẹ̀KỌ́ 1: YÍYÀN TÍ Ó WỌ́PỌ̀ ÀTI ÀWỌN ÀTÚNBỌ̀TÁN RẸ̀
A. Onírúurú àwọn nǹkan tí à ń yàn láyé ló ní àtúnbọ̀tán tiwọn. Fún àpẹẹrẹ:
i. Ìrúfẹ́ óunjẹ tí a yàn láti máa jẹ́ àti eré ṣíṣe ní ipá lórí ìlera ara wa (Owe 25:16).
ii. Irúfẹ́ ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí a yàn láti kà máa ń sáàbà kó ipa pàtàkì lórí irúfẹ́ isẹ́ tí a fẹ ṣe àti ẹni tí a fẹ́ jẹ nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́.
iii. Irúfẹ́ ohun tí a yàn lórí ìhá ti a kọ sí ìsẹ̀lẹ̀ inú ayé yìí nípá lórí ìgbé ayé àlàáfíà wa (Owe 24:10).
iv. Ìrúfẹ́ yíyàn tí a yàn láti yàtọ̀ lè sọ bóyà a máa jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀ láwùjọ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tàbí bẹ́ẹ̀kọ́ (Dan 1:8, 19; Heb 11:24-26).
v. Irúfẹ́ yíyàn tí a yàn bóyá kí a sin Ọlọ́run tàbí bẹ́ẹ̀kọ yóò sọ nípa irúfẹ́ èrè ayérayé tí a máa gbà (Josua 24: 15, Ifihan 22:11-12).
IṢẸ́ ṢÍṢE NÍ KÍLÁÀSI KÍNNÍ: Kíni a lè ṣe láti yẹra fún àwọn àtúnbọ̀tán àṣìyàn tí a ti yàn?
ÌLÀNÀ Ẹ̀KỌ́ 2: ÀWỌN OHUN TÍ Ó NÍ IPÁ LÓRÍ YÍYÀN
A. i. Ọgbọ́ntí óyẹ: A nílò láti wá ọgbọ́n tí ó yẹ kí á bàá lè mọ bí nǹkan ṣe ńlọ sí (Owe 18;15)
ii. Ìkọ́ra-ẹni-níjanu: Eléyìí yóò ran yíyàn wa lọ́wọ́ àti pé yóò dènà wa láti máṣe ṣe ìpinnu tí kò yẹ.
iii. Ṣíṣètò àti ìran: A gbọ́dọ̀ sèsò tí ó dára kí a sì jẹ́ kí ìran dídára jẹ́ atọ́nà fún wa kí á tó yan ohunkóhun (Rutu 3:1-4; Owe 16, 3, 9).
iv. Àdúrà: Pàtàkì ni èyí jẹ́ àdúrà yóò rànwálọ́wọ́ láti tẹ̀lé ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún wa (1Sam. 30:7-8; Orin Daf. 37:5, 23).
v. Pa ọkàn rẹ mọ́: A gbọ́dọ̀ làkàkà láti máa ro èrò rere nígbà gbogbo. (Owe 4:23)
B. Lọ́nà mìíràn, ìgbéraga, àgàbàgebè, iyèméjì àti èròkerò àti àwọn nǹkan mìíran bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ ìdènà fún wa láti yàn dáradára (Owe 11:2, Orin Dafidi 10:4, Isaiah 32:6, Jakọbu 1:8).
IṢẸ́ ṢÍṢE NÍ KÍLÁÀSI KEJÌ: Kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jíròrò lórí àwọn okùnfà mìíràn tí ó lè nípá lórí bí àwọn ènìyàn se ń yàn.
(3) ÌSỌNÍṢỌ́KÍ: Ohun tí a yàn nílé ayé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ okunfà ní ipá lórí rẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ ló ní àtúnbọ̀tán.
(4) ÌKÁDÌÍ: Tí a bá tí yan èyí tí kò dára látẹ̀hìnwá, àsìkò tó báyìí láti dárìjì ara wa kí a sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú ayé wa gẹ́gẹ́ bí a ó ṣe àwọn àtúnṣe tí ó yẹ kí a ṣe kí irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀ má bàá wáyé mọ́.
(5) ÌGBÉLÈWỌ̀N: Dárúkọ àwọn yíyàn tó wọ́pọ̀ àti àwọn àtúnbọ̀tán wọn.
(6) ÀDÚRÀ ÌPARÍ: Baba, jọ̀wọ́ rànmílọ́wọ́ láti yàn lọ́nà ti Ọlọ́run nígbà gbogbo ní orúkọ Jésù.
(7) ISẸ́ ÀSETILÉWÁ: Dárúkọ̀ ọ̀nà márùn ún (5) tí ohun tí o yàn ti ní ipa rere tàbí búburu lórí rẹ (Máàkì Mẹ́wàá).

Leave a Reply

Open Heavens Daily Devotional guide was written by Pastor E.A. Adeboye, the General Overseer of the Redeemed Christian Church of God, one of the largest evangelical church in the world and also the President of Christ the Redeemer’s Ministries. The Open Heavens devotional application is available across all mobile platforms and operating systems: iOS, Android, Blackberry, Nokia, Windows Mobile and PC.

Discover more from Open Heavens and RCCG Daily Publications

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading