YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL Ẹ̀KỌ́ KEJÌLÁ OHUN ÌJÌNLẸ̀ NÍPA ÀÌSEDÉÉDÉ
ALL RCCG MANUALS THIS WEEK
- RCCG SUNDAY SCHOOL STUDENTS’ MANUAL SUNDAY 20TH OF NOVEMBER 2022 LESSON TWELVE (12)
- FRENCH RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL Leçon 12 LE MYSTÈRE DE L’INIQUITÉ DIMANCHE 20 NOVEMBRE 2022
- YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL Ẹ̀KỌ́ KEJÌLÁ OHUN ÌJÌNLẸ̀ NÍPA ÀÌSEDÉÉDÉ
- RCCG JUNIOR ZEAL AGE 13-19 TEACHER’S MANUAL SUNDAY 20TH OF NOVEMBER 2022 LESSON 12
- RCCG HOUSE FELLOWSHIP LEADERS’ MANUAL SUNDAY, 20TH NOVEMBER, 2022 LESSON TWELVE (12)
- RCCG YAYA SUNDAY SCHOOL STUDENTS’ MANUAL SUNDAY 20TH OF NOVEMBER 2022 LESSON TWELVE (12)
- RCCG YAYA SUNDAY SCHOOL TEACHERS’ MANUAL SUNDAY 20TH OF NOVEMBER 2022 LESSON TWELVE (12)
- RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHERS’ MANUAL SUNDAY 20TH OF NOVEMBER 2022 LESSON TWELVE (12)
BÍBÉLÌ KÍKÀ: 2 Tẹsalonika 2:1-12.
1. ṢUGBỌN awa mbẹ̀ nyin, ará, nitori ti wíwa Jesu Kristi Oluwa wa, ati ti ipejọ wa sọdọ rẹ̀,
2. Ki ọkàn nyin ki o máṣe tete mì, tabi ki ẹ máṣe jaiya, yala nipa ẹmí, tabi nipa ọ̀rọ, tabi nipa iwe bi lati ọdọ wa wá, bi ẹnipe ọjọ Oluwa de.
3. Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni tàn nyin jẹ lọnakọna; nitoripe ọjọ na ki yio de, bikoṣepe ìyapa nì ba kọ́ de, ki a si fi ẹni ẹ̀ṣẹ nì hàn, ti iṣe ọmọ ègbé;
4. Ẹniti nṣòdì, ti o si ngbé ara rẹ̀ ga si gbogbo ohun ti a npè li Ọlọrun, tabi ti a nsin; tobẹ ti o joko ni tẹmpili Ọlọrun, ti o nfi ara rẹ̀ hàn pe Ọlọrun li on.
5. Ẹnyin kò ranti pe, nigbati mo wà lọdọ nyin, mo nsọ̀ nkan wọnyi fun nyin?
6. Ati nisisiyi ẹnyin mọ ohun ti o nṣe idena, ki a le ba fi i hàn li akokò rẹ̀.
7. Nitoripe ohun ijinlẹ ẹ̀ṣẹ ti nṣiṣẹ ná: kìki pe ẹnikan wà ti nṣe idena nisisiyi, titi a ó fi mu u ti ọ̀na kuro.
8. Nigbana li a ó si fi ẹ̀ṣẹ nì hàn, ẹniti Oluwa yio fi ẽmi ẹnu rẹ̀ pa, ti yio si fi ifihan wíwa rẹ̀ sọ di asan:
9. Ani on, ẹniti wíwa rẹ̀ yio ri gẹgẹ bi iṣẹ Satani pẹlu agbara gbogbo, ati àmi ati iṣẹ-iyanu eke, 10. Ati pẹlu itanjẹ aiṣododo gbogbo fun awọn ti nṣegbé; nitoriti nwọn kò gbà ifẹ otitọ ti a ba fi gbà wọn là.
12. Ati nitori eyi, Ọlọrun rán ohun ti nṣiṣẹ iṣina si wọn, ki nwọn ki o le gbà eke gbọ́: Ki a le ṣe idajọ gbogbo awọn ti kò gbà otitọ gbọ́, ṣugbọn ti nwọn ni inu didùn ninu aiṣododo.
ẸSẸ̀ ÀKỌ́SÓRÍ: Nitorí pé ohun ìjìnlẹ̀ ẹ̀sẹ̀ tí nsiṣẹ́ náà kìkì pé ẹnìkan wà tí ń n ṣe ìdènà nísisìyí, títí a ó fi múu ti ọ̀nà kúrò” 1Tẹsalonika 2:7.
ÀFIHÀN: Ìjìnlẹ̀ jẹ́ ohun kan tí n da òye ẹni láàmú tì ènìyàn kò lè ṣàlàyé rẹ̀. Ó jẹyọ láti inú ọrọ tí a pè ní mysterium pẹ̀lú ọ̀rọ̀ gíríkì “musterion” tí ó túmọ̀ sí àsírí. Ẹ̀sẹ̀ jẹyọ láti inú ọ̀rọ̀ tí a pè ní “anomia” (ni Gíríkì) túmọ̀ sí àìtọ́ tínṣe rírú òfin tàbí ìwà búburú títasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin àìsòdodo tàbí àìpa òfin mọ́. Nítorí náà, ìjìnlẹ̀ ti ẹ̀sẹ̀ jẹ́ ìlànà rírú òfin tí aṣe ìkìlọ̀ rẹ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ tí o sì yẹ láti máa kíyèsíi.
ÀWỌN ÌLÀNÀ Ẹ̀KỌ́
1. BÍ A ṢE ṢÀLÀYÉ OHUN ÌJÌNLẸ̀ NÍPA ÀÌSEDÉÉDÉ
2. ÀWỌN ONÍGBÀGBỌ́ GBỌ́DỌ̀ MÁA ṢỌ́NÀ
1. BÍ A ṢE ṢÀLÀYÉ OHUN ÌJÌNLẸ̀ NÍPA ÀÌSEDÉÉDÉ
Ìjìnlẹ̀ ti ẹ̀sẹ̀ jẹ́ láti máṣe pa òfin mọ́ nínú ayé tí ó sì wa yọrí sí ìsọ̀tẹ̀ lòdì sí Ọlọ́run (Mat.24:12, 2Tim.3:1-4) O jẹ́ nípa ṣíṣe àkóso àti ìdarí àwọn ènìyàn, àgbékalẹ̀ ìlànà, ìṣúna abbl (Gẹn.11:4).
Ó jẹ́ ìlànà tí ó lágbára kan tí ó ti dárapọ tàbí rápálá wọ inú òṣèlú, ìdárayá, ètò ẹ̀kọ́, ẹ̀sìn, ayélujára abbl (Rom.1:21-22). A tún ṣe àfihàn rẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹ̀tàn àti àwọn ẹ̀kọ́ ti èṣù (2Tim.3:13, 1Tim.4:1). Ó ṣe àfihàn àwọn ohun okunkun nínú ayé ènìyàn (Iṣe Apo 8:22-23, Mat.23:28) Ẹ̀sẹ̀ máa n bá ọkan wa rẹ́ jùlọ (Mak.7:21-23) tí ó sì máa bá àwọn èróngbà wa sọ̀rọ̀ láti ṣe àyípadà àgbékalè ìwà mímọ́ Ọlọ́run (Juda 4). Ó máa ń ti àwọn ènìyàn láti yí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run po (Tit.1:11) Dájúdàjú ní ọjọ́ kan yóò fi ara hàn gẹ́gẹ́ bí aṣòdì sí Kristi, tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bẹ́ lójú iṣẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú ayé ṣùgbọ́n tí a múso nísisìyí kí ayé má baá di ohun ibi gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹ́ (2Tẹs.2:7-8, 1Joh.4:3).
IṢẸ́ ṢÍṢE KÍLÁÀSÌ KÍNNÍ: Kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dárúkọ èyíkèyí ipa èyítí ìjìnlẹ̀ ẹ̀sẹ̀ tí n ṣiṣẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ àti báwo ni ó ṣe ń ṣeé?
2. ÀWỌN ONÍGBÀGBỌ́ GBỌ́DỌ̀ MÁA ṢỌ́NÀ
Pẹ̀lú ẹ̀mí àìpa òfin mọ tímbẹ káàkiri nínú ayé, àwọn onígbàgbọ́ gbọ́dọ̀:
1. Yẹ ọkàn wọn wọ̀, KÍ WỌ́n sì pa ọkàn náà mọ́ dáradára àti ní ìgbà gbogbo Joeli 2:13, Owe 4:23).
2. Jẹ́wọ́ èyíkèyí ẹ̀sẹ̀ tí wọ́n mọ̀ (1Joh.1:9). Kí wọ́n sì ronúpìwàdà láti gbà ìdáríjì lọ́dọ̀ Olúwa (Iṣe Apo 3:19).
3. Kí wọ́n máṣe dàpọ̀ mọ́ ayé yìí (Rom.12:2) kí wọ́n sì máa ṣe takuntakun láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ (Deut.1:22).
4. Ẹ máa ṣọ́nà kí ẹ sì máa gbàdúrà (Mat.26:41).
5. Gbé Ọkùnrin ọ̀tun wọ̀ (Kol.3:10) kí o sì máa di ẹni ọ̀tun lóòrè-kóòrè nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ (Titu 3:5).
6. Yẹra kúrò nínú ẹ̀sẹ̀ (2Tim.2:19) kí o sì mú gbogbo ìwúkàrà ògbólògbó ẹ̀sẹ̀ náà kúrò (1Kọr. 5:7).
7. Wẹ ara wọn nù (2Tim.2:21) kí asọ wọ́n sì jẹ́ aláìlábà wọ́n (Oniw 9:8).
IṢẸ́ ṢÍṢE KÍLÁÀSÌ KEJÌ: Kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dárúkọ bí wọ́n ṣe bá ìdánwọ̀ kan wí lọ́wọ́lọ́wọ́.
ÌPARÍ: Àwọn onígbàgbọ́ gbọdọ̀ mọ̀ wípé ẹ̀mí tín tàpá sí òfin tín jẹgàba nínú ayé lọ́wọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n sì ríi dájú pé wọn pa iṣẹ́ ìgbàgbọ́ wọn mọ́ títí dé òpin.
ÌBÉÈRÈ:
* Kíni ìjìnlẹ̀ ti ẹ̀sẹ̀?
* Dárúkọ àwọn ohun mẹ́rin tí àwọn onígbàgbọ́ lè ṣe láti máa sọ́nà.
ISẸ́ ÀMÚRELÉ: Dárúkọ ipa márùn-ún tí ayé lè gbà tàn ọ́ láti jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ tí tí ayérayé. Fún àpẹrẹ lílọ̀ sí ilé ijọ máàkì mẹ́wàá.