\
Home » RCCG JUNIOR ZEAL TEACHER'S » YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL ỌGBỌ̀NJỌ́, OSÙ KẸWÀÁ, ỌDÚN 2022 Ẹ̀KỌ́ KẸSÀN-ÁN

YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL ỌGBỌ̀NJỌ́, OSÙ KẸWÀÁ, ỌDÚN 2022 Ẹ̀KỌ́ KẸSÀN-ÁN



Subscribe to Blog via Email

Enter your email address to subscribe to this blog and receive notifications of new posts by email.

Table of Contents

BÍBÉLÌ KÍKÀ: Nehemiah 5:14-19.

14. Pẹlupẹlu lati akoko ti a ti yàn mi lati jẹ bãlẹ wọn ni ilẹ Juda, lati ogún ọdun titi de ọdun kejilelọgbọn Artasasta ọba, eyinì ni, ọdun mejila, emi ati awọn arakunrin mi kò jẹ onjẹ bãlẹ.
15. Ṣugbọn awọn bãlẹ iṣaju, ti o ti wà, ṣaju mi, di ẹrù wiwo le lori awọn enia, nwọn si ti gbà akara ati ọti-waini, laika ogoji ṣekeli fadaka; pẹlupẹlu awọn ọmọkunrin wọn tilẹ lo agbara lori enia na: ṣugbọn emi kò ṣe bẹ̃ nitori ibẹ̀ru Ọlọrun.
16. Mo si mba iṣẹ odi yi lọ pẹlu, awa kò si rà oko kan: gbogbo awọn ọmọkunrin mi li o si gbajọ sibẹ si iṣẹ na.
17. Pẹlupẹlu awọn ti o joko ni tabili mi jẹ ãdọjọ enia ninu awọn ara Juda ati ninu awọn ijoye, laika awọn ti o wá sọdọ wa lati ãrin awọn keferi ti o wà yi wa ka.
18. Njẹ ẹran ti a pese fun mi jẹ malũ kan ati ãyo agutan mẹfa; fun ijọ kan ni a pese adiẹ fun mi pẹlu, ati lẹ̃kan ni ijọ mẹwa onirũru ọti-waini: ṣugbọn fun gbogbo eyi emi kò bere onjẹ bãlẹ, nitori iṣẹ na wiwo lori awọn enia yi.
19. Ranti mi, Ọlọrun mi, fun rere, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti mo ti ṣe fun enia yi.
ẸSẸ̀ ÀKỌ́SÓRÍ: Nígbà tí àwọn olódodo wà lórí oyè, àwọn ènìà a yọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí ènìà búburú bá gorí oyè, àwọn ènìyàn á kẹ́dùn. Owe 29:2.
ÀFIHÀN: Lápapọ̀, ètò ìṣélú ni a lè ṣàpéjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣètò àti ṣíṣe aápọn tó rọ̀mọ́ ìṣèjọba, ilé-iṣẹ́ tàbí ìṣèlú níṣe pẹ̀lú níní ipá/agbára lórí ẹni. Agbára/ipá yìí ní yóò bí ìyípadà rere tàbí búburú nínú ayé àwọn ènìyàn. Dídásí àwọn Kristẹni nínú ìsèlú kìí ṣe tí ayé, tàbí tí ó kọjá ìgbé ayé Kristẹni ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìfẹ́ inú Ọlọ́run fún àwọn onígbàgbọ́ pé kí wọ́n ṣàkóso, kí wọ́n sì lágbára lórí ilẹ̀ ayé (Gẹn.1:28; Matt.5:13-16).
YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL ỌGBỌ̀NJỌ́, OSÙ KẸWÀÁ, ỌDÚN 2022 Ẹ̀KỌ́ KẸSÀN-ÁN

ÀWỌN ÌLÀNÀ Ẹ̀KỌ́

1. ÈRÒ ÒDÌ NÍPA ÌṢÈLÚ
2. KÍNI ÌDÍ TÍ KRISTẸNI FI GBỌ́DỌ̀ LỌ́WỌ́SÍ ÌṢÈLÚ?
1. ÈRÒ ÒDÌ NÍPA ÌṢÈLÚ
Àwọn Kriṣtẹni Kan gbà pé níwọn ìgbà tí ìjọba wa kìí ṣe ti ayé yìí, a nílò láti lọ́wọ́sí ètò ìṣèlú Kánkán nínú ayé tí à ń gbé báyìí (Joh.17:14). Eléyìí kìí ṣe òtítọ́ rárá ṣùgbọ́n èrò òdì ni tí ó ṣetán láti jà wá lólè ogún ìní jíjọba tí Ọlọ́run ní fún wa. (Orin Daf.8:6; 1 Pet.2:9, Ifi.5:10) Lára àwọn ìdí fún èrò òdì tàbí ìmọ̀ òdì nípa lílọ́wọ́sí àwọn Kristẹni nínú ìṣèlú ni a mẹ́nubà níbí yìí;
1. Ètò ìṣèlú jẹ́ ohun àìmọ́ àti ti ayé.
2. Lílọ́wọ́sí ètò ìṣèlú yóò mú ènìyàn dé ọ̀run àpáàdì.
3. Gbogbo àwọn olóṣèlú jẹ́ òpùrọ̀, oníwà ìbàjẹ́ àti onìdàrúdàpọ̀.
4. Ó jẹ́ àǹfààní láti kówójẹ tàbí kó owó jọ lọ́nà àìtọ́.
5. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olòṣèlú ni wọ́n jẹ́ olóògùn tàbí aláwo.
IṢẸ́ ṢíṢe Kíláàsì Kínní: Kíni ìdí tí àwọn ènìyàn fi ń bẹ̀rù ìṣèlú?
YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL ỌGBỌ̀NJỌ́, OSÙ KẸWÀÁ, ỌDÚN 2022 Ẹ̀KỌ́ KẸSÀN-ÁN

2. KÍNI ÌDÍ TÍ KRISTẸNI FI GBỌ́DỌ̀ LỌ́WỌ́SÍ ÌṢÈLÚ?

Láti lè yí èrò wa padà gẹ́gẹ́ bí Kristẹni nípa ìlọ́wọ́sí wa nínú ètò ìṣèlú, a nílò láti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn èrèdí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ wọ̀nyí.
(1) Ó jẹ́ inú dídùn Ọlọ́run fún onígbàgbọ́ láti ṣàkóso; kí a sì ní ipá lórí ilé ayé yìí. (Deut.28:13). Àwa lóyẹ ká ṣíwájú, kí a sì fààyè gba ìdíyelé ti ìjọba láti tún àwùjọ wa ṣe (Matt.5:13-16).
(2) Adarí tí a yàn, tàbí kùnà láti yàn ní ipá/ agbára ńlá lórí òmìnira wa ìgbé ayé àti ìmúṣe àwọn ohun tí Ọlọ́run pa láṣe fún wa láti múṣẹ. Wọ́n lè yàn láti dáàbò bo ẹ̀tọ́ wa láti jọ́sìn, kí a sì tan ìhìnrere kálẹ̀, tàbí ṣe ìdènà fúnwa láti ṣe ẹ̀tọ́ wa yìí̀ (Esteri 4:14, Dan.6:7).
(3) Ìṣèlú gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun mìíràn tí ń nmú orílẹ̀ èdè dàgbà (ìlera ètò ìṣúná owó, abbl) ni a gbọ́dọ̀ lò láti fi “kọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè” láti lè ṣàfihàn ìgbé ayé tí ó ní àpẹẹrẹ rere ti ìwà-bi-Ọlọ́run (Dan.6:1-3, Mat.28:19-20).
(4) Lílọ́wọ́sí àwọn Kristẹni ọmọ Ọlọ́run nítòótọ́ nínú òṣèlú yóò dín ìwà ìbàjẹ́, àìlétò, ìwà ìkà àti àwọn ìwà ìpanilára mìírán kù láwùjọ (2Kron.14:1-6; Owe 29:2).
(5) Láti lè ṣátúnṣe dí dára, tí yóò sì pẹ́, yóò sì sẹ àǹfààní fún àwùjọ (Gẹn.41:33-40; Owe 14:34).
IṢẸ́ ṢíṢe Kíláàsì Kejì
Kíni àwọn onígbàgbọ́ lè ṣe láti mú ẹ̀rù kíkùnà tàbí ìjákulẹ̀ kúrò nínú ìṣèlú.
ÌPARÍ: Ọlọ́run ṣì ń ṣàwárí àwọn olódodo díẹ̀, fún ìgbéga orílẹ̀ èdè wa. (Gẹn.18:32).

ÌBÉÈRÈ

* Dárúkọ èrò òdi mẹ́rin (4) tí àwọn onígbàgbọ́ ní nípa ìṣèlú.
* Kíni ìdí tí Kristẹni fi gbọ́dọ̀ lọ́wọ́sí ètò ìṣèlú?
ISẸ́ ÀMÚRELÉ: Dárúkọ àwọn àtúnbọ̀tán márùn ún fún yíyàn tàbí dídìbò yan aláìwà-bi-Ọlọ́run/Àwọn ènìyàn buburu láti darí (Máàkì Méjì Fún Kókó Kọ̀ọ̀kan=Máàkì Mẹ́wàá).

Leave a Reply

Open Heavens Daily Devotional guide was written by Pastor E.A. Adeboye, the General Overseer of the Redeemed Christian Church of God, one of the largest evangelical church in the world and also the President of Christ the Redeemer’s Ministries. The Open Heavens devotional application is available across all mobile platforms and operating systems: iOS, Android, Blackberry, Nokia, Windows Mobile and PC.

Discover more from Open Heavens and RCCG Daily Publications

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading