\
Home » RCCG Sunday School Manual » YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL Ẹ̀KỌ́ KEJÌDÍNLỌ́GBỌ̀N: ỌJỌ́ KÈJÌLÁ, OSU KẸTA, ỌDÚN 2023

YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL Ẹ̀KỌ́ KEJÌDÍNLỌ́GBỌ̀N: ỌJỌ́ KÈJÌLÁ, OSU KẸTA, ỌDÚN 2023



Subscribe to Blog via Email

Enter your email address to subscribe to this blog and receive notifications of new posts by email.

Table of Contents

IWE ILE EKO OJO ISINMI TI OLUKO TI ODUN 2023
IWE ILE EKO OJO ISINMI TI OLUKO TI ODUN 2023
<

Paycheap.ng

YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL

Ẹ̀KỌ́ KEJÌDÍNLỌ́GBỌ̀N: ỌJỌ́ KÈJÌLÁ, OSU KẸTA, ỌDÚN 2023 –

AKORI: Ẹ̀SÌN ÌGBÀGBỌ́ ÀTI ỌRỌ̀

ÀDÚRÀ ÌBẸ̀RẸ̀: Baba, fi ìbùkún sí iṣẹ́ ọwọ́ mi kí o sì bùkún fún ìlàkàkà mi pẹ̀lú ojúrere.
ÌMỌ̀ ÀTẸ̀HÌNWÁ: Kí olùkọ́ fi àyè gba akẹ́kọ̀ọ́ láti mú ohun gbogbo tì wọn ti kọ́ wá sí ìrántí nínú ẹ̀kọ́ ti ọ̀sẹ̀ tó kọ́já “Jíjá àjàga òṣì Dànù.
BÍBÉLÌ KÍKÀ: Luku 12:15-21 BM
15. O si wi fun wọn pe, Kiyesara ki ẹ si mã ṣọra nitori ojukòkoro: nitori igbesi aiye enia ki iduro nipa ọ̀pọ ohun ti o ni.
16. O si pa owe kan fun wọn, wipe, Ilẹ ọkunrin kan ọlọrọ̀ so eso ọ̀pọlọpọ:
17. O si rò ninu ara rẹ̀, wipe, Emi o ti ṣe, nitoriti emi kò ni ibiti emi o gbé kó eso mi jọ si?
18. O si wipe, Eyi li emi o ṣe: emi o wó aká mi palẹ, emi o si kọ́ eyi ti o tobi; nibẹ̀ li emi o gbé tò gbogbo eso ati ọrọ̀ mi jọ si.
19. Emi o si wi fun ọkàn mi pe, Ọkàn, iwọ li ọrọ̀ pipọ ti a tò jọ fun ọ̀pọ ọdún; simi mã jẹ, mã mu, mã yọ̀.
20. Ṣugbọn Ọlọrun wi fun u pe, Iwọ aṣiwere, li oru yi li a o bère ẹmi rẹ lọwọ rẹ: njẹ titani nkan wọnni yio ha ṣe, ti iwọ ti pèse silẹ?
21. Bẹ̃ li ẹniti o tò iṣura jọ fun ara rẹ̀, ti ko si li ọrọ̀ lọdọ Ọlọrun.
ẸSẸ̀ ÀKỌ́SÓRÍ: ”Ọrọ̀ pẹ̀lú àti ọlá ọ̀dọ̀ rẹ ni ti íwá, ìwọ si jọba lórí ohun gbogbo; li ọwọ rẹ ni agbára àti ipá wa; àti li ọwọ rẹ ni sisọ ni din la wa, àti fifi agbára fún ohun gbogbo ” 1 Kronika 29:12.
FIHÀN: Ẹ̀SÌN ÌGBÀGBỌ́ ÀTI ỌRỌ̀
Ọrọ̀ ni níní ohun ìní tàbí owó tí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Nígbà tí a bá lọ́rọ̀, a ní ju àwọn ohun tí a nílò lọ tí o yẹ́ kí o mu ayé kan dẹrùn. Bíbélì kún fún oríṣiríṣi àwọn àpẹẹrẹ ènìyàn tí Ọlọ́run bùkún pẹ̀lú ọrọ̀ ńlá; Abraham (Gẹn.13:2), Jákọ́bù (Gẹn.30:43), Sólómọ́nì (1Awọn ọba 10:23), Jòánà (Luk.8:3) àti Jósẹ́fù àti àwọn mìíràn. A fẹ́ gbéyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa ọrọ̀ àti ohun tí ó yẹ kí ó jẹ́ ìhá tí àwọn onígbàgbọ́ gbọ́dọ̀ kọ síi.
ÀKỌSÍLẸ̀ OLÙKỌ
ÌLÉPA Ẹ̀KỌ́: Láti kọ́ nípa ìwòye bíbélì nìpa ọrọ̀ àti ìhá tí àwọn onígbàgbọ síi.
ÈRÒǸGBÀ ÌKỌ́NÍ: Nípaṣẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí, àwon akẹ́kọ̀ọ́ yóò lè:
a. Ní òye nípa ohun ti Bíbélì wí nípa ọrọ̀. b. Ṣàwárí bi a ṣe lè pẹ̀lú ọrọ̀ lọ́nà ti Ọlọ́run.
ÈTÒ ÌKỌ́NI: Láti lè ṣe àwọn èróńgbà òkè yìí, olùkọ́ gbọ́dọ̀ :
a. Fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ laye láti dárúkọ àpẹerẹ àwọn ènìyàn tí ó ní ọrọ̀ nínú Bíbélì. b. Dárúkọ àwọn àpẹẹrɛ ẹsẹ̀ Bíbélì tí ó ń tọ́kasí pé láti ọ̀dọ Ọlọ́run ní ọrọ̀ ti wá àti wípé Ọlọ́run kò lòdì síi. d. Kìlọ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lórí ewu tí ó wà nínú lílé ọ̀rọ̀ tipátipá. e. Dárúkọ ọ̀nà tí ó tọ́ láti ní ọrọ̀ láìdẹ́sẹ̀. ẹ Jíròrò lórí iṣẹ́ ṣíṣe ti kíláásì méjèèjì. f. Ṣe àkópọ̀, àkótán, ìgbéléwọ̀n ẹ̀kọ́, gba àdúrà ìparí kí o sì fún wọn ní iṣẹ́ àṣetiléwá.
ÀTÚNYẸ̀WÒ BÍBẸ́LÌ KÍKÀ: Luku 12:15-21.
A. Kí olùkọ́ ṣàwárí àwọn ọ̀rọ̀ kúkurú tàbí awé gbólóhùn tàbí gbólóhùn tí ó ní “Èmi” tàbi “EMI” nínú látinú ẹsẹ̀ bíbélì yìí.
i. Ẹsẹ̀ 17b -Kíni kí “Emi” ó ṣe?
ii. ———————————-
iii.———————————-
iv.———————————
v.———————————-
B. Kíni àwọn àtúnbọ̀tán síso ọrọ̀ mọ́ isẹ́ tí a se gẹ́gẹ́ bí Ẹsẹ̀ Ogún ti wí?
ÀWỌN ÌLÀNÀ Ẹ̀KỌ́
1. OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
2. ÌHÀ TÍ ÀWỌN ONÍGBÀGBỌ́ GBỌ́DỌ̀ KỌ SÍI
1. OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
A. Kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dárúkọ àpẹẹrẹ àwọn ènìyàn tí ó lọ́rọ̀ nínú Bíbélì ní àfikún àwọn ènìyan tí a dárúkọ nínú àfihàn ẹ̀kọ́.
B. Kí olùkọ́ darí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ sí ipò tí Bíbélì dúró lè lórí ọrọ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí:
i. 1 Kronika 29:12 Ọlọ́run ló ni ọrọ̀ àti ọlá.
ii. Deut 28:1-5: Ọlọ́run máa ń bùkún àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ àti ọ̀lá.
iii. Orin Daf. 112:1-3: Ilé àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò kún fún owó àti ọrọ̀.
iv. Owó kìí ṣe ohun búburú, nítorí pé:
a. Oniwasu 10:19 wípé owó ni ìdáhùnsí ohun gbogbo.
b. Oniwasu 7:12 wípé owó jẹ́ ìdáàbòbò.
d. Owe 19:4 wípé owo máa ń ní ọ̀rẹ́ púpọ̀.
v. Oniwasu 5:19: Láti jẹ̀gbádùn ọrọ̀ ti ènìyàn ní jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
D. Látinú àwọn kókó òkè wọ̀nyí, kí olùkọ́ bèrè lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ sọ bóyá ọrò àti owó dára fún onígbàgbọ́ láti ní tàbí bẹ́ẹ̀kọ́.
E. Kí olùkọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ láyè láti dárúkọ àwọn ohun wọnnì tí kò dára nípa ọrọ̀. Fún àpẹẹrẹ:
i. Ìfẹ́ owo kò dára nítorí pé ó jẹ gbòǹgbò ohun búburú (1Tim 6:10).
ii. Níní ìgbẹkẹ̀lé nínú owó kò dára. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run tí ó ni gbogbo owó ló yẹ kí á gbọ́kànlé. (Owe 23:5, Luke 12:15).
iii. Níní ọrọ̀ nípasẹ̀ àwọn ọ̀nà tó lòdì kò dára nítorí pé irúfẹ́ ìlọ́rọ̀ bẹ́ẹ̀ yóò parẹ́ (Owe 13:11)
iv. Rírí ọrọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run, kó lòdì kò dára nítorí pé ìwọ yóò kú lọ́jọ́ kan tí ìwọ yóò si fi ọrọ̀ yìí sílẹ̀ (Orin Daf. 49:10).
v. Wíwá owó débi wípé a kò bìkítà fún àwọn ohun mìíràn tí ó ṣe pàtàkì nílé ayé kò dára nítorí pé asán ni ọrọ̀ àti wípé àwọn tí ó ń lé e kò lè ní ìtẹ́lọ́run láéláé (Oniwasu 5:10a).
IṢẸ́ ṢíṢE KÍLÁÀSÌ KÍNNÍ: Kí kíláásì jíròrò lórí àwọn okùnfà òṣì mìíràn láìdárúkọ àwọn tí ó wà lókè yìí.
2. ÌHÀ TÍ ÀWỌN ONÍGBÀGBỌ́ GBỌ́DỌ̀ KỌ SÍI
Àwọn kókó tí a kọ sísàlẹ̀ wọ̀nyí lè mú kí ènìyàn bọ́ nínú òṣì:
i. Ṣàwárí rẹ̀ kí ó sì tẹ̀lé èrèdí ìwàláàyè rẹ (Owe 22:29).
ii. Mú ara rẹ̀ dàgbà síi nínú isẹ́ tí o bá yàn láàyo, isẹ́ kíkọ́ tàbí ọjà títà (Owe 18;15, 24:4).
iii. Jẹ́ kí ọ̀nà tí owó ń gbà wọlé fún ọ ju ẹyọ̀kan lọ. (Oniwasu 11:2).
iv. Yanjú ìṣòro àwọn ènìyàn
v. Ní ọgbọ́n kún ọgbọ́n nípa lílo fún ìdanilẹ́kọ̀ọ́ síi lórí iṣẹ tí ó ń ṣe
vi. Ní ìgbàgbọ́ nínú agbára rẹ láti ṣàṣeyọrí (Filipi 4:13).
vii. Jẹ́ ẹni tó ń fifúni dáradára (Owe 11:24).
viii. San ìdámẹ́wàá rẹ, èso àkọ́kọ́ àti ọrẹ nígbà gbogbo (Mal 3:10-12, Owe 3:9-10).
ix. Gbàdúrà kí ọ sì ka ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ìtọ́ni (Orin 37:23).
x. Máṣe jẹ́ onígbèsè, yá owó láti ṣòwò nìkan (Owe 22:7).
Kristẹni gbọ́dọ̀ kíyèsí pé ọrọ̀ kò fìgbà kan jẹ́ òdinwọ̀n déédé fún ìdúróṣinṣin ènìyàn pèlú Ọlọ́run. Àwọn Olódodo kan wà tí wọ́n tòṣì (Luk.16:20-23) nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kan jẹ ọlọ́rọ̀ (O.Daf.73:3, 12). Báwo wá ni kí onígbàgbọ́ láti jẹ̀gbádùn ìlọ́rọ wọn (Oniw.5:19; 3Joh.2), wọ́n gbọ́dọ̀ rí ọrọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdókòwò tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ (1Kron.29:12); wọ́n gbọ́dọ̀ lo ọrọ̀ yìí láti ṣerere kí wọ́n sì máa lé èrèdí ti Ọlọ́run.
Àwọn ọlọ́rọ̀ onígbàgbọ́ lè ṣàgbékalẹ̀ ètò ṣíṣàánú àti fífún àwọn ènìyàn ní ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, ṣíṣètò ìtọ́jú fún àwọn ọmọ aláìlóbìí, opó àti àwọn tí nǹkan kò lọ déédé fún (1Joh.3:17-18, Jak.1:27), Kí o sì jẹ́ ohun èlò nínú ìmúgbòòrò ìjọba Ọlọ́run (Luk.8:3, Romu 16:3). Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn onígbàgbọ́ fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí Olótitọ́ ọwọ ọ̀dọ̀. Nípa ṣíṣàmúlò ọrọ̀ wọn fún Ọlọ́run (1Kor.4:2, Mat.6:19-20).
IṢẸ́ ṢÍṢE KÍLÁÀSÌ KEJÌ: Kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jíròrò lórí àwọn ọ̀nà Ọlọ́run mìíràn láti bọ kúrò nínú òṣì.
ÀKOJỌPỌ̀: A kò dá òṣì mọ́ àyànmọ́ ẹnikẹ́ni nítorí náà ṣe àyípadà èrò ọkàn rẹ kí o sì mọ̀ pé Ọlọ́run ló ń fún ni lágbára láti ní ọrọ̀ (Deut 8:18).
ÌPARÍ: Láti ní ọrọ̀, àwọn onígbàgbọ́ gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ìọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ ló yẹ kí àwọn kọ́kọ́ wá ná (Mat.6:32).
ÌBÉÈRÈ
* Darúkọ ohun mẹ́ta (3) tí bíbélì sọ nípa ọrọ̀.
* Báwo ló ṣe yẹ kí oníbàgbọ́ ṣe pẹ̀lú ọrọ̀?
ÌYÀNNÀNÁ: Báwo ni a ṣe lè dojúkọ òṣì?
ÀDÚRÀ ÌPARÍ: Baba ọ̀run, jọ̀wọ́ fún mi ní ọrọ̀ àti ọlá púpọ̀ kí o sì lè òṣì jìnnà réré sími.
ISẸ́ ÀMÚRELÉ: Dárúkọ ohun márùn ún tí onígbàgbọ́ gbọdọ ko gbọdọ̀ ṣe nínú bíbéèrè láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ (Máàkì Mẹ́wàá).

Leave a Reply

Open Heavens Daily Devotional guide was written by Pastor E.A. Adeboye, the General Overseer of the Redeemed Christian Church of God, one of the largest evangelical church in the world and also the President of Christ the Redeemer’s Ministries. The Open Heavens devotional application is available across all mobile platforms and operating systems: iOS, Android, Blackberry, Nokia, Windows Mobile and PC.

Discover more from Open Heavens and RCCG Daily Publications

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading