\
Home » RCCG JUNIOR ZEAL TEACHER'S » YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL ỌJỌ́ KỌKÀNDÍNLỌ́GBỌ̀N, OSU KÍNNÍ, ỌDÚN 2023.

YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL ỌJỌ́ KỌKÀNDÍNLỌ́GBỌ̀N, OSU KÍNNÍ, ỌDÚN 2023.


Table of Contents

YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL ỌJỌ́ KỌKÀNDÍNLỌ́GBỌ̀N, OSU KÍNNÍ, ỌDÚN 2023.

AKORI: ÀWẸ̀ GBÍGBÀ NÍNÚ BÍBÉLÌ

ÀDÚRÀ ÌBẸ̀RẸ̀: Baba, rànmí lọ́wọ́ láti lóye nípa àgbékalẹ̀ bíbélì fún ááwẹ̀ gbígbà.
ÌMỌ̀ ÀTẸ̀HÌNWÁ: Kí olùkọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láyè láti ṣe àtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́ ti ọ̀sẹ̀ tó kọja.
BÍBÉLÌ KÍKÀ: Daniẹli 10:2-3.
2. Li ọjọ wọnni li emi Danieli fi ikãnu ṣọ̀fọ li ọ̀sẹ mẹta gbako.
3. Emi kò jẹ onjẹ ti o dara, bẹ̃ni kò si si ẹran tabi ọti-waini ti o wá si ẹnu mi, bẹ̃li emi kò fi ororo kùn ara mi rara, titi ọ̀sẹ mẹta na fi pe.
ẸSẸ̀ ÀKỌ́SÓRÍ: ”Èmi sì kọjú sí Olúwa Ọlọ́run, láti ma ṣàfẹ́rí nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú àwẹ̀, nínú aṣọ-ọ̀fọ̀ àti erú.” Daniẹli 9:3.
ÀFIHÀN: Àwẹ̀ gbígba, nínú Bíbèlì, ni yíyàgò pátápátá kúrò nínú àwọn ìṣesí tí ó ń múni jẹ̀gbádùn fún ìgbà díẹ̀, láti farajìn fún wíwá ojú Ọlọ́run. Nígbà tí onírúurú ọ̀nà wà fún àwọn onígbàgbọ́ tí wọ́n lè fi gbààwẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà, ìfojúsùn wọn ni yíyàgò fún oúnjẹ. Nínú ẹ̀kọ́ yìí, á ó gbéyẹ̀wò oríṣiríṣi àwẹ̀ gbígbà nínú Bíbélì, àwọn ìkìlọ̀ àti èrèdí fún gbígba ààwẹ̀.
YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER'S MANUAL
YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL
<

Paycheap.ng
ÈRÒǸGBÀ ÌKỌ́NÍ: Nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò lè:
a. Ṣọ ìtumọ̀ àwẹ̀ gbígba ti inú Bíbélì.
b. Ṣàlàyé orísiríṣi àwẹ̀ gbígbà ti inú bíbélì.
d. Tọ́ka sí àwọn èrèdí fún àwẹ̀ gbígbà ti inú bíbélì. e. Dárúkọ àwọn ohun tí ó yẹ láti yàgò fún nínú gbígba àwẹ̀ ti inú bíbélì.
ÈTÒ ÌKỌ́NI: Láti lè ṣe èróńgbà yìí, Kíí olùkọ́:
a. Fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ka ẹsẹ̀ àkọ́sórí, bíbélì kíkà, dá sí ìjíròrò, ṣe iṣẹ́ ṣíṣe ti kíláásì àti isẹ́ àṣetiléwá wọn. b. Fààyè sílẹ̀ fún igbákejì olùkọ́ láti mójútó kíláásì, kí ó sì buwọ́lùwé wíwásí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti iṣẹ́ àṣetiléwá. d. Kọ́ ìlànà ẹ̀kọ́ méjèèjì, ṣe àkópọ̀, àkótán, ìgbéléwọ̀n ẹ̀kọ́ àti fún akẹ́kọ̀ọ́ ní iṣẹ́ àṣetiléwá.
ÀTÚNYẸ̀WÒ BÍBẸ́LÌ KÍKÀ: Daniẹl 10:2-3.
Wòólì Dáníẹ́lì jẹ́ ọkùnrin tí ó kún fún Ẹ̀mí Ọlọ́run àti ìmọ̀ rẹ̀. Ní onírúurú ọ̀nà, Ó ṣàfihàn ìfarajìn àìsiyèmejì rẹ̀ sí Ọlọ́run. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà yì́ ni àwẹ̀ gbígbà. Ẹsẹ̀ Bíbélì yìí ṣe àkọsílẹ̀ rẹ pé:
i. Ó fi ìkáàánú ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, ẹsẹ̀ 2.
ii. Ó————————————————— ẹsẹ̀ 3a.
iii. —————————————————- ẹsẹ̀ 3b.
iv. Bẹ́ẹ̀ni òun kò———————————-ẹsẹ̀ 3d.
v. Títí————————————————– ẹsẹ̀ 3e.

ÀWỌN ÌLÀNÀ Ẹ̀KỌ́

1. ORÍṢIRÍṢI ÀWẸ̀ NÍNÚ BÍBÉLÌ
2. ÈRÈDÍ ÀTI ÀWỌN ÌKÌLỌ̀
1. ORÍṢIRÍṢI ÀWẸ̀ NÍNÚ BÍBÉLÌ
Kí olùkọ́ kọ́kọ́ sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n dárúkọ orìṣirisí àwẹ̀ tí wọ́n mọ̀ lẹ́yìn ìgbà yìí ní kí o dárúkọ oríṣirisi àwẹ̀ tí wọ́n mọ, lẹ́yìn ìgbà yìí ní kí o dárúkọ orísíi àwẹ̀ ìsàlẹ̀ yìí:
(a) Àwẹ̀ ti oúnjẹ.
(b) Àwẹ̀ ti ìbálọ̀pọ̀.
(d) Àwẹ̀ ti jíjẹ ìgbádùn.
Kí olùkọ́ ṣàlàyé ọ̀kọ̀ọkan àwọn kókó tí a kọ sókè wọ̀nyí báyìí:
1. ÀWẸ̀ OÚNJẸ: Eléyìí ni yíyàgò fún ọúnjẹ/ohun mímu. Ó lè tẹ̀lé ìlànà wọ̀nyí:
(i) ÀWẸ̀ ÌGBÀ GBOGBO: Eléyìí ni à ń ṣe nípasẹ̀ yíyàgò fún gbogbo oúnjẹ, Òkèlè àti olómi (2 Kron. 20:3) Irúfẹ́ àwẹ̀ yìí jẹ́ èyí ti à n já lójoojúmọ́ tàbí ìgbà díẹ̀ (Jer.36:6).
(ii) ÀWẸ̀ TÍ KÒ KÚN: Wòólì Dáníẹ́lì ni ó fi èyí lélẹ̀. Gbogbo ẹran àti nǹkan ẹranko ni kò fàáyè gbà. Àwẹ̀ Dáníẹ́lì yìí jẹ́ ti Ewébẹ̀, ẹ̀fọ́ lórísìrísi, àwọn irúgbị̀n, èso lóríṣirísi àti omi. Àwọn ìlànà yìí dúró lè ohun tí Dáníẹ́lì bèrè fún ní tip é “kò sí ohunkóhun bíkoṣe ewébẹ̀ láti jẹ àti omi fún mímu” (Dan.1:8-14).
(iii) ÀWẸ̀ PÍPÉ TÀBÍ KÍKÚN: Níbi tí kò ní sí oúnjẹ tàbí mímu omi rárá (Esteri 4:16; Iṣe Apo 27:33). Fún àpẹẹrẹ, Mósè, Èlíjàh, àti Jésù Kristi Olúwa àwẹ̀ ogójì ọjọ́ àpẹẹrẹ Mósè, Èlíjàh àti Jésù Kristi Olúwa àwẹ̀ ogójì ọjọ́ láìfi ohunkóhun kan ẹnu (Deut.9:9; 1Ọba 19:7-8; Luku 4:2).
2. ÀWẸ̀ ÌBÁLÒPỌ̀: Bíbélì tún mẹ́nuba àwẹ̀ ìbálòpọ̀” (Eks.19:15). Àwọn tọkọtaya lè jùmọ̀ panupọ̀ láti yàgò fún ìbálòpọ̀ fún ìgbà díẹ̀ láti lè fara wọn jìn fún àdúrà. (1Kọr.7:5).
3. ÀWẸ̀ ÀRÍYÁ: Ọ̀nà mìíràn ni láti wa nínú ìséraẹni tàbí yàgò fún àwọn ènìyàn àti nǹkan àríyá sí ibìkan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti jọ́sìn, ṣàṣàrò nínú ọ̀rò Bíbélì àti gbígbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìdí pàtàkì kan (Luk.`2:36-37, 5:16). Àkokò dídánìkan wà pẹ̀lú Ọlọ́run nílò ìkóra-ẹni-níjanu.
IṢẸ́ ṢÍṢE KÍLÁÀSÌ KÍNNÍ: Nípasẹ̀ títẹ̀le ohun tí ìwé mímọ́ wí, ǹ jẹ́ òfin kan wà tí ó sọ̀rọ̀ nípa àkokò tí ó yẹ kí á já ààwẹ̀ wa?
2. ÈRÈDÍ ÀTI ÀWỌN ÌKÌLỌ̀
A. Àwẹ̀ jẹ́ wíwa ojú Ọlọ́run ju yíyàgò fún ohun jíjẹ tàbí àwọn ohun mìíràn tí ó ń fún ni ní ìgbádùn (Zech 7:5).
B. Àwọn ènìyàn máa ń gbààwẹ̀ fún oríṣirísi ìdí. Àwọn mìíràn fún:
i. Okun ti Ẹ̀mí (Isa 40:30-31).
ii. Ìfihàn àtòkèwá ìmọ̀ àti ọgbọ́n (Esra 8:21, Dan. 9:3-5).
iii. Àlùyọ àtòkèwá (Zech 8:19).
iv. Ìyípadà kúrò nínù ẹ̀sẹ̀ dídá (Joeli 2:12-13; Dan 9:3-5).
v. Ìpòùǹgbẹ ti Ẹ̀mí àti fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run àti ìkáàánú fún àwọn ọkàn (2kọr. 11:27-28, Mat. 5:6).
vi. Bíbá àwọn òtòsi ̀ ṣe alájọpín àti pípa isẹ́ búburú run, àti àwọn ohun mìíràn (Isa 58:6-7).
D. Àwọn onígbàgbọ́ gbọ́dọ̀ kíyèsára nínú ààwẹ̀ gbígbà wọn:
i. Àwẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ gbígbà fún ìwọ̀nba ìgbà díẹ̀, Ó sì gbọ́dọ̀ ní dìí (1Kọr. 7:5; Esteri 4:16).
ii. Kìí ṣe nítorí láti fi ìyà jẹ ara tàbí ọ̀nà láti dín oúnjẹ ku (Isa 58:5) ṣùgbọ́n láti kọ ojú wa pada sí Ọlọ́run.
iii. Ó jẹ́ àsìkò láti yàgò fún ìṣẹ ti ara fún ìbáṣepọ̀ tí ó jinlẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run (Matt. 4:1-2).
iv. Kò sẹ́ni tí kò lè gba àwè ṣùgbọ́n àwọn kan le mále gbà àwẹ̀ láìjẹ́un nítorí àìléra wọn. Àmọ́ síbẹ̀síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló lè fi ohun kan sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ láti súnmọ́ Ọlọ́run síi (Eksodu 19:15).
v. Àwẹ̀ gbígbà ti bíbélì ni a níláti se nínú irẹ̀lẹ̀ àti ayọ̀ kíkún (Mat 6:16-18).
vi. Kìí ṣe láti ṣe màdàrú tàbí ohun búburú (Isa 58:4a, Iṣe Apo 23:21).
vii. Ní jíjá ááwẹ̀ bíríbírí tàbí ọlọ́jọ́ pípẹ́, omi tó lọ́ wọ́rọ́, (kìí ṣe ọtí ẹlẹ́rìndodo) ni a gbà wá níyànjú láti mu, kí a sì mú ún díẹ̀ díẹ̀.
Àwẹ̀ níṣe pẹ̀lú fífojúsùn Ọlọ́run ju yíyàgò fún oúnjẹ àti àwọn ohun àríyá ti ń mú ìdùnnú wa fún wa (Sek.7:5) Bákan náà, àwọn ènìyàn máa ń gbààwẹ̀ fún onírúurú èrèdí. Àwọn mìíràn fún okun ti Ẹ̀mí (Isa.40:30-31), Ìsípayá àtòkèwá (Sek.8:19) ìrònúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ dídá (Joeli 2:12-13, Dan.9:3-5), Òǹgbẹ Ẹ̀mí àti fífi ìfẹ́ hàn fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run àti ìkáànú fún àwọṅ ọkàn (2 Kọr.11:27-28; Mat.5:6) àti àjọpín pẹ̀lú àwọn otòsì àti pípa iṣẹ́ àwọṅ ẹni búburú run, àti àwọn nǹkan mìíràn (Isa.58:6-7).
Àwọn onígbàgbọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ fún àkokò kan àti fún èrèdí kan pàtó (1 Kọr.7:5; Est.4:16). Kìí ṣe láti jẹ ara níyà tàbí ọna láti dín oúnjẹ jíjẹ kù ni kí a ṣe gbàá (Isa.58:5) ṣùgbọ́n láti ṣíjú wa padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ó jẹ́ àkokò láti pa isẹ́ tí ó ń díwa lọ́wọ́ tì fún ìbáṣepọ tí ó jinlẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run (Mat.4:1-2). Ẹnikẹ́ni ló lè gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn kan lè málè yẹra fún oúnjẹ (Fún àpẹẹrẹ ẹni tí ó ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà). Síbẹ̀síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló lè pa nǹkan kan tì fún ìgbà díẹ̀ láti súnmọ́ Ọlọ́run síi (Eks.19:15).
Àwẹ̀ gbígbà ti bíbélì gbọ́dọ̀ di ṣíṣe pẹ̀lú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti tayọ̀tayọ̀ (Mat.6:16-18). Kò gbọdọ̀ jẹ́ láti ṣe àlúpàyídà tàbí ṣe ohun búburú (Isa.58:4a; Iṣe Apo 23:21) Láti já àwẹ “pípẹ́ àti ọlọ́jọ́ gbọọrọ, Omi tó lọ́ wọ́ọ́rọ́. (Kìí ṣe ọti ẹlẹ́riǹ dòdò) ni a gbàwá nímọ̀ràn láti mu àti kí á sì mú díẹ̀díẹ̀.
IṢẸ́ ṢÍṢE KÍLÁÀSÌ KEJÌ: Ǹ jẹ́ àìlè lo àkokò tí ó dára nínú àdúrà gbígbà pa ààwẹ̀ gbígbà rẹ́ bí?
ÀKOJỌPỌ̀: Onírúurú ọ̀nà àti èrèdí ló wà tí àwọn onígbàgbọ́ fi lè gba ààwẹ̀ àti pé ìkíyèsára nàà wà láti lè ṣe bí lọ́nà tí yóò fibá bíbélì mu.
ÌPARÍ: Bèrè ọgbọ́n lọ́wọ́ Ọlọ́run (Jakọbu 1:5) lórí báwo àti fún ọjọ́ mélòó àti kíni èrèdí tí ó fi ní kí o gbààwẹ̀.

ÌBÉÈRÈ:

* Dárúkọ oríṣirísi àwẹ̀ nínú Bíbélì
* Dárúkọ ìdí mẹ́ta tí àwọn onígbàgbọ́ fi gbààwẹ̀ nínú Bíbélì.
ÌYÀNNÀNÁ: Kíni idi rẹ̀ ti a fi nílò láti tẹramọ́ àdúrà gbígbà?
ÀDÚRÀ ÌPARÍ: Baba, jọ̀wọ́ fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ láti máa gbàdúrà láìsinmi nínú ìgbé ayé àdúrà mi
ISẸ́ ÀMÚRELÉ: Dárúkọ ànfààní márùn ún tí a lè rígbà nínú gbígba àwẹ̀ (Máàkì Mẹ́wàá).

Leave a Reply

Open Heavens Daily Devotional guide was written by Pastor E.A. Adeboye, the General Overseer of the Redeemed Christian Church of God, one of the largest evangelical church in the world and also the President of Christ the Redeemer’s Ministries. The Open Heavens devotional application is available across all mobile platforms and operating systems: iOS, Android, Blackberry, Nokia, Windows Mobile and PC.

Discover more from Open Heavens and RCCG Daily Publications

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading