YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL Ẹ̀KỌ́ KẸRÌNLÉLÓGÚN ỌJỌ́ KEJÌLÁ, OSU KEJI, ỌDÚN 2023.
AKORI: ÈSO TI Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ (APÁ KEJÌ)
ÀDÚRÀ ÌBẸ̀RẸ̀: Baba, rànmílọ́wọ́ láti lóye bí mo ṣe lè so èso òdodo.
ÌMỌ̀ ÀTẸ̀HÌNWÁ: Kí olùkọ́ ṣe àtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́ ti ọ̀sẹ̀ tó kọja.
BÍBÉLÌ KÍKÀ: Galatia 5:16-18.
16. Njẹ mo ni, Ẹ ma rìn nipa ti Ẹmí, ẹnyin kì yio si mu ifẹkufẹ ti ara ṣẹ.
17. Nitoriti ara nṣe ifẹkufẹ lodi si Ẹmí, ati Ẹmí lodi si ara: awọn wọnyi si lodi si ara wọn; ki ẹ má ba le ṣe ohun ti ẹnyin nfẹ.
18. Ṣugbọn bi a ba nti ọwọ Ẹmí ṣamọna nyin, ẹnyin kò si labẹ ofin.
ẸSẸ̀ ÀKỌ́SÓRÍ: ”Èso òdodo li à ń gbìn lí àlàáfíà fún àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àláfíà.” Jakọbu 3:18.
ÀFIHÀN: Ìgbé ayé Kristẹni jẹ ogun láarin ìṣẹ́dà wa sínú ẹ́ṣẹ̀ àti ẹ̀dá tuntun ti a jẹ nínú Kristi (Gal.5:17) ṣùgbọ́n, nítorí pé a ti gba Jésù kò sọ pé a ti ni àjẹsára sí ìdánwò ẹ̀sẹ̀ (Rom.7:14-25). Nígbà mìíràn ó máa ń ṣe wá bíi wípé kí a ni ìfẹ́ láti tọwọ́ bọ nǹkan tó jẹ́ ẹ̀sẹ̀ ju ohun tii ṣe ti Ọlọ́run. Eléyìí kò yẹ kí ó máa ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo. A lè borí ẹran ara.
ALSO, READ
- RCCG JUNIOR ZEAL FOR 2022/2023 AGE 9-12 TEACHER’S MANUAL FOR 12TH OF FEBRUARY, 2023
- RCCG LOWER JUNIOR ZEAL FOR 2022/2023 AGE 4-5 TEACHER’S MANUAL SUNDAY 12TH OF FEBRUARY, 2023
- RCCG JUNIOR ZEAL FOR 2022/2023 AGE 13-19 TEACHER’S MANUAL SUNDAY 12TH OF FEBRUARY, 2023
- YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL OSU KEJI ỌDÚN 2023
- FRENCH RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL Leçon 24 DIMANCHE 12 FÉVRIER 2023
- RCCG YAYA SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL LESSON 24 12TH OF FEBRUARY 2023
- RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHERS’ MANUAL SUNDAY 12TH OF FEBRUARY, 2023
ÀKỌSÍLẸ̀ OLÙKỌ
ÌLÉPA Ẹ̀KỌ́: Láti kọ́ nípa bí a ṣe lè so èso Ẹ̀mí.
ÈRÒǸGBÀ ÌKỌ́NÍ: Nípaṣẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, àwon akẹ́kọ̀ọ́ yóò lè:
a. Lóye nípa bí a se lè yàn sísó èso. b. Mọ́ bí wọn ṣe lè ṣe iṣẹ́ ìgbàlà wọn.
ÈTÒ ÌKỌ́NI: Láti lè ṣe èróńgbà òkè yìí, kí olùkọ́ :
a. Fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ka ẹsẹ̀ àkọ́sórí, bíbélì kíkà, dá sí ìjíròrò, ṣe iṣẹ́ ṣíṣe ti kíláásì àti isẹ́ àṣetiléwá wọn. b. Fààyè sílẹ̀ fún igbákejì olùkọ́ láti mójútó kíláásì, kí ó sì buwọ́lùwé wíwásí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti iṣẹ́ àṣetiléwá. d. Kọ́ ìlànà ẹ̀kọ́ méjèèjì, ṣe àkópọ̀, àkótán, ìgbéléwọ̀n ẹ̀kọ́ àti fún akẹ́kọ̀ọ́ ní iṣẹ́ àṣetiléwá.
ÀTÚNYẸ̀WÒ BÍBẸ́LÌ KÍKÀ: Galatia 5:16-18.
A. Pọ́ọ̀lù Aposteli gba àwọn ará Gálátíà níyànjú lórí bí a ṣe lè borí ẹ̀sẹ̀ àti òfin. Ó wí fún wọn pé kí————————————–ẹsẹ 16.
B. Èrèdí fún ọ̀rọ̀ yìí ni pé
i. Ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ——————..——-ẹsẹ 17a.
ii. Àwọn wọ̀nyí ni ——————————ẹsẹ 17b.
iii. Wọn kò lè ————————————ẹsẹ 17d.
iv. Wọn kò lè ————————————-ẹsẹ 18.
D. Ṣùgbọ́n tí—————————————ẹsẹ 18.
ỌGBỌ́N ÌKỌ́NI: Ọgbọ́n ìkọ́ni ọlọ́rọ̀ geere.
LÍLÒ ÀKÓKÒ: Kí olùkọ́ pín àkokò ẹ̀kọ́ yìí sórí kíkọ́ ìlànà ẹ̀kọ́ mejèèjì.
ÀWỌN ÌLÀNÀ Ẹ̀KỌ́
1. YÀN LÁTI SO ÈSO
2. ṢIṢẸ́ FÚN UN
1. YÀN LÁTI SO ÈSO
A. Nísinsìnyí tí a ti wà nínú Kristi, a ní agbára láti sẹ́gun níní ìfẹ́ láti dẹ́ṣẹ̀ tíí ṣe ti ara (2Kọr. 5:17, Romu 8:37)
B. Ìwà láàyè Ẹ̀mí mímọ́ nínú ọkàn wa túmọ̀ sí pé a lè yan ìwà-bí-Ọlọ́run yàtọ̀ sí ẹ̀sẹ̀ (Filipi 1:21-22).
i. Ọwọ́ wan i yíyàn yìí wà pátápátá (Deut 30:19).
ii. Àwa kìí ṣe ẹrú mọ́ sí ẹ̀sẹ̀ (Rom 6:14, 18).
iii. A lè yan ìfẹ́ lórí ìkórira, sùúrù lórí ìkanra ìbànújẹ́, ìṣòtítọ́ lórí àìdúróṣinṣin, ìkóra-ẹni-níjanu lórí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ abbl.
D. Eléyìí ni adùn níní Ẹ̀mí mímọ́- Ó máa ń fi AGBÁRA fún ni láti jà (Filipi 2:13, 4:13).
E. Gbogbo ohun tí a nílò láti ṣe kí á lè rí agbára yìí gbà ni láti ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìtọ́ni rẹ̀ (Jn 15:4, 10, 14, Kolose 3:16, Orin Daf. 1:2-3).
Nísinsinyí tí a ti wà nínú Kristi a ní agbára láti ṣẹ́gun ìfẹ́ ẹran ara láti dẹ́sẹ̀ (2Kọr.5:17, Rom.8:37). Ẹ̀mí mímọ́ tí ń gbé nínú ọ̀kan wa túmọ̀ sí pé a lè yan ìwà-bí-Ọlọ́run láàyọ̀ ju igbé ayé ẹ̀ṣẹ̀ (Filp.1:22). Yíyàn yìí ku si wa lọ́wọ́ pátápátá (Deut.30:19).
Àwa kìí ṣe ẹrú ẹ̀sẹ̀ mọ (Romu 6:14, 18). A lè yan ìfẹ́ lórí ìkórìra, sùúrù lórí ìkanra ìpinlẹ́mìí, ìṣòtítọ́ lórí àìṣòtitọ, ìkora-ẹni-níjanu lórí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ abbl. Eléyìí ni adùn níní Ẹ̀mí mímọ́. Ó fún wa ní AGBÁRA láti jà (Filp.2:13:, 4:13) Gbogbo ohun tí a níláti ṣe láti ní ìrírí agbára yìí ni ṣíṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìtọ̀ni rẹ̀ (Joh.15:4, 10, 14; Kol.3:16; O.Daf.1:2-3).
IṢẸ́ ṢÍṢE KÍLÁÀSÌ KÍNNÍ: Kí kíláásì jíròrò ìyàtọ̀ díẹ̀ tí ó wà láarín ìmọ̀lára àti ṣíṣàfihàn ẹ̀bun ti Ẹ̀mí.
2. ṢIṢẸ́ FÚN UN
A. Àwọn Kristẹni kan ti bèrè bóyá ó seéṣe láti ní gbogbo èròjà èso tí Ẹ̀mí yìí tí ń ṣe ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni-níjanu. Eléyìí dàbí pé ó pọ̀ láti ṣiṣé lé lóri.
(i) A ní láti rántí pé Ọlọ́run kò ní fún wa ní ẹrù ti a kò ní lè gbé (Matt 11:29-30).
(ii) “Àjàgà” ti síso èso ti Ẹ̀mí mímọ́ kìí ṣe ohun tí ó ṣeé ṣe nìkan sùgbọ́n kànńpa ni (Lk 1:37, Matt 5:48).
B. Síbẹ̀síbẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ọ̀tá ìgbàlà wa- èṣù àti ẹran ara-kò ní sinmi lórí wa nírọ̀rùn, a ní láti dojúkọ ìdánwò ti dídá ẹ̀sẹ̀ lẹ́ẹ́kọ̀ọ̀kan (1Pet 5:8-10).
D. A gbọ́dọ̀ tẹ̀síwájú láti máa:
i. Ṣisẹ́ láti jé pípé (Filipi 2:12).
ii. Jọ̀wọ́ pátápátá fún àṣẹ Ẹ̀mí mímọ́ kí a sì kọ ojú ìjà sí Èṣù (Jakọbu 4:7).
iii. Má ṣe gba ẹran ara láàyè (Romu 13:14).
iv. ṣiṣẹ́ láti ní gbogbo èròjà èso ti Ẹ̀mí, kí o sì gbàgbọ́ pé yóò ṣe é ṣe (Filipi 4:13).
v. Lójoojúmọ́, gbé ìgbésẹ̀ láti mú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Jésù dàgbà kí a bàá lè dàgbà síi láti rí bíi rẹ̀ nínú ìwà, ìsọ̀rọ̀ àti ìṣesí (Heb 12:2, Filipi 2:5).
Àwọn Kristẹni, kan ti bèrè bóyá ó seése láti ní gbogbo ẹ̀yà èso ti Ẹ̀mi wọ̀nyí tíí ṣe ìfẹ́, ayọ̀, àlàfíà, ípamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣore, ìsọ̀títọ́ àti ìkóra-ẹni níjanu. O dàbí pé eléyìí pọ̀ láti ṣiṣẹ́, lè lórí. Lákọkọ́, a nílati rántí pé Ọlọ́run kò ní fún wa ní ẹrù tí a kò nílè gbé lọ (Mat.11:29-30). Ìkeji ̀, àjàgà síso éso ti ẹ̀mí mímọ́ kìí ṣe pé ó ṣe éṣe nìkan ṣùgbọ́n ó pọn dandan (Luk.1:37, Mat.5:48). Síbẹ̀síbẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ọ̀tá ìgbàlà wa- èṣù àti ẹran ara-kò ní fi wá silẹ̀ nírọ̀rùn, a nílàti dojúkọ ìdánwò láti dẹ́sẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan (1 Pet.5:8-10). A gbọ́dọ̀ tẹ̀síwájú láti máa ṣiṣẹ́ fún àti jẹ́ ẹni pípé (Filp.2:12) Jọ̀wọ́ ara rẹ pátápátá fún ìdarí Ẹ̀mí mímọ́ kí ó sì ko ojú ìjà sí ẹ̀sù (Jak.4:7) Páùlù Aposteli sọ fún àwọn onígbàgbọ́ láti máṣe pèsè fún ara (Rom.13:14). Ẹ jẹ́ kí a tẹ́síwájú láti máa ṣiṣẹ́ fún síso gbogbo ẹya èso ti Ẹ̀mi mímọ́; Ó ṣeéṣe (Filp.4:13). A níláti máa gbé ìgbésẹ̀ lójoojúmọ́ láti máa tọ́jú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Jésù kí a bàá lè dàgbà láti dàbí rẹ̀ nínú ìhùwàsí, ìṣesí àti ìgbésẹ̀ wa (Heb.12:2, Filp.2:5).
IṢẸ́ ṢÍṢE KÍLÁÀSÌ KEJÌ: Kí kíláàsì dárúkọ àwọn ìgbésẹ̀ mìíràn tí onígbàgbọ́ lè gbé láti ní gbogbo èso ti Ẹ̀mí.
ÀKOJỌPỌ̀: Gbogbo onígbàgbọ́ ló ye kó yàn láti so èso ti Ẹ̀mí kí wọ́n sìṣiṣẹ́ láti lè di ẹni pípé.
ÌPARÍ: Lótitọ́ a lè làkàkà kí a sì kùnà, O dájú pé a máa sẹ́gun ẹran ara, a ó sìso èso ti Ẹ̀mí mímọ́. A gbọ́dọ̀ máa fi ojoojúmọ́ tiraka, ṣiṣẹ́ fún àti pòùngbẹ fún èso ti Ẹ̀mí.
ÌBÉÈRÈ:
* Ǹjẹ́ síso èso jẹ́ yíyàn bí? Báwo?
* Ǹjẹ́ a lè so gbogbo àwọn èso wọ̀nyí? Báwo?
ÌYÀNNÀNÁ: Kí ni kí onígbàgbọ́ ṣe láti so èso ti Ẹ̀mí?
ÀDÚRÀ ÌPARÍ: Baba, jọ̀wọ́ fún mi ní oore ọ̀fẹ́ láti ní gbogbo èròjà ti èso ti Ẹ̀mí.
ISẸ́ ÀMÚRELÉ: Kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dárúkọ ìdí márùn ún (5) tí ó fi pàtàkì fún onígbàgbọ́ láti so èso ti Ẹ̀mí (Máàkì Mẹ́wàá).