\
Home » RCCG JUNIOR ZEAL TEACHER'S » YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL ỌJỌ́ KARÙN ÚN OSU KEJI ỌDÚN 2023

YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL ỌJỌ́ KARÙN ÚN OSU KEJI ỌDÚN 2023

Support the Good work on this Blog

CLICK HERE TO SUPPORT US

God Bless you


Table of Contents

ÀDÚRÀ ÌBẸ̀RẸ̀:
Baba, jọ̀wọ́ rànmílọ́wọ́ nínú ìlàkàkà mi láti kọ́ bí a ṣe ń gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run ní orúkọ Jesù.

BÍBÉLÌ KÍKÀ: Galatia 5:22-23.

22. Ṣugbọn eso ti Ẹmí ni ifẹ, ayọ̀, alafia, ipamọra, ìwa pẹlẹ, iṣore, igbagbọ́,
23. Ìwa tutù, ati ikora-ẹni-nijanu: ofin kan kò lodi si iru wọnni.
ẸSẸ̀ ÀKỌ́SÓRÍ: ”Nítorí èso Ẹ̀mí wà níti ìṣore gbogbo àti òdodo, àti òtitọ́.” Efesu 5:9.
ÀFIHÀN: Ọ̀kan lára àwọn ìdí tí Jésù fi fúnwa ní Ẹ̀mi Mímọ́ ni láti rànwálọ́wọ́ láti kọ́ bí a se le gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run (Joh.16:12-15). Ẹ̀mí mímọ́ yóò fi òye ẹ̀sẹ̀ wa yéwa (Joh.16:8) yóò sì ṣatọ́nà wa nínú yíyàn dáradára nígbà tí ìdánwò bá kojú wa, èyí tí yóò mu ìwà-bí Ọlọ́run jáde nínú wa (Efe.3:16; Joh.16:13). Eléyìí ni bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “Èso ti Ẹ́mí.
ÀKỌSÍLẸ̀ OLÙKỌ
ÌLÉPA Ẹ̀KỌ́: Láti kọ́ nípa èso ti Ẹ̀mí Mímọ́
ÈRÒǸGBÀ ÌKỌ́NÍ:
: Lẹ́yìn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò lè:
a. Tọ́kasí èso ti Ẹ̀mí. b. Ṣàlàyé ìdí tí ìwe mímọ́ fi ṣàmúlò fífi èso ṣàkàwé.
d. Mọ̀ nípa àbájáde àìsèèso ti Ẹ̀mí
ÈTÒ ÌKỌ́NI: Láti lè ṣe èróńgbà òkè yìí, kí olùkọ́ :
a. Fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ka ẹsẹ̀ àkọ́sórí, bíbélì kíkà, dá sí ìjíròrò, ṣe iṣẹ́ ṣíṣe ti kíláásì àti isẹ́ àṣetiléwá wọn. b. Fààyè sílẹ̀ fún igbákejì olùkọ́ láti mójútó kíláásì, kí ó sì buwọ́lùwé wíwásí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti iṣẹ́ àṣetiléwá. d. Kọ́ ìlànà ẹ̀kọ́ méjèèjì, ṣe àkópọ̀, àkótán, ìgbéléwọ̀n ẹ̀kọ́ àti fún akẹ́kọ̀ọ́ ní iṣẹ́ àṣetiléwá.
ÀTÚNYẸ̀WÒ BlÍBẸ́LÌ KÍKÀ: Galatia 5:22-23.
Pọ́ọ̀lù Aposteli, nígbà tí ó ń bá àwọn ará Gálátíà sọ̀rọ̀ (Gbogbo Kristẹni ni eléyìí wà fún) láti kúrò nínú àwọn isẹ́ tí ń se ti ara, èyí tí ó ń fiwọ́n sínú ìgbèkùn òfin, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n jẹ́ kí ẹ̀mí máa darí wọn. Ó tún pé àkíyèsí wọn sí àbájáde kíkún fún ẹ̀mí mímọ́ pé:
i. Èso ti Ẹ̀mí ni ————————–ẹsẹ 22-23a.
ii. Pọ́ọ̀lù pé ——————————-ẹsẹ 23b.

ÀWỌN ÌLÀNÀ Ẹ̀KỌ́

1. KÍNI ÌDÍ TÍ Ó FI JẸ́ ÈSO?
2. LÌDÀKEJÌ SÍSO ÈSO
1. KÍNI ÌDÍ TÍ Ó FI JẸ́ ÈSO?
A. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkàwé ohun ọ̀gbìn ni Bíbélì ṣàmúlò rẹ̀ nítorí pé ó rọrùn láti tètè lóye rẹ̀ pẹ̀lú àkokò ìfúrúgbìn.
B.”Èso ti Ẹ̀mi yìí túmọ̀ sí “àbájáde” tí a gbọ́dọ̀ rí nínú ayé wa lẹ́yìn tí a gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí mímọ́ tí ó sì ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkàn wa.
D. Pọ́ọ̀lù Àpóstélì fún waní èròjà inú “èso gẹ́gẹ́ bí”….. ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, ìwà tútù,ìkóra-ẹni-níjanu…….Gal 5:21-22.
E. “Èso” tí a fi ṣàkàwé yìí rànwálọ́wọ́ láti rí ìgbàgbọ́ wa gẹ́gẹ́ bí igi tí ó ní ẹ̀ka tí ó lè mú èso jáde tàbí bẹ́ẹ̀kọ, tí ó níṣe pẹ̀lú bí a ṣe bójútó igi náà tó.
i. Tí a bà fún igi yìí ni oúnjẹ (Òrọ̀ Ọlọ́run)- 1Pet 1:23, 2:2, nígbà náà ni yóò tóbi síi.
ii. Tí a bá roko abẹ́ rẹ̀ àti mu àwọn kòkòrò kúrò (ìwà ẹ̀ṣẹ̀)-(Efesu 4:22-31, Col 3:8-10), nígbà náà ni igi yìí yóò wà ní ìlera.
iii. Tí a bá ọ̀rọ̀ náà tó ọjọgbọn alágbàṣẹ létí (Ọlọ́run)-1Kronika 16:11- nígbà náà ni a ní ìdánilójú pé ohun tí ó tọ́ ni à ń ṣe.
Bíbélì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ákáwé nítorí pé ó rọrùn láti tètè ní òye rẹ̀ nípasẹ̀ àṣà tó rọ̀mọ́ ọgbọ́n níti àkokò àti ìgbà. “Èso ti Ẹ̀mí ń tọ́ka sí “abájáde èsì tí a gbọ́dọ̀ rí nínú ayé wa lẹ́yìn tí a gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí mímọ́ tí ó si ńfi ìgbàgbogbo ṣiṣẹ́ nínú ọkàn wa. (Rom.8:19; 12:1-2). Paul Aposteli fún wa ní èròjà ti èso yìí gẹ́gẹ́ bí Ìfẹ́, ayọ, alááà. Ìpamọ́ra. Ìṣoore, ìwà pẹ̀lẹ́, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-nijanu (Gal.5:21-22).
Ọ̀rò àkàwé ti “èso” tí a lò yìí rànwalọ́wọ́ láti rí ìgbàgbọ́ wa gẹ́gẹ́ bí igi tí ó ní ẹ̀ka tí ó lè mú èso jáde tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, tí ó nífi ṣe pẹ̀lú bí a ṣe ń se ìtọ́jú igi náà tó. Tí a bá fún igi yìí ni oúnjẹ tí yóò mú un dára (Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run) – (1Pet.1:23; 2:2) yóò dàgbà sókè dáràdára. Tí a bà ro oko ìdí rẹ̀ tí a sì lè kòkòrò jìnà síi (èyí ni ẹ̀sẹ̀)- Efe.4:22-31; Kol.3:8-10, àìsàn kò ní ṣe igi yìí. Tí a bá pe olùsọ́gbà tí ó kojú òsùwọ̀n (Ọlọ́run) láti dá síì- 1Kron.16:11- eléyìí yóò mu dáwalojú pé a wà ní ọ̀nà tí ó tọ́.
IṢẸ́ ṢíṢe KÍLÁÀSÌ KÍNNÍ:
Ǹ jẹ́ ó ṣe éṣe fún Kristiẹni tó kún fún Ẹ̀mí mímọ́ láti má ṣàfihàn lára àwọ èròjà ti èso ti Ẹ̀mí mímọ́? Tí o bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, ṣàlàyé.
2. ÌDÀKEJÌ SÍSO ÈSO
A. Tí o bá jẹ́ Kristẹni tí o kò ṣàfihàn èso ti ẹ̀mí nínu ayé rẹ:
i. Lákọkọ́, ìwọ yóò ní ìrírí ìdádúró láìdàgbàsókè (Jakọbu 2:14-26).
ii. Èyí tó burú jùlọ, àbájáde “èso búburú” ni ikú (Romu 6:20-23, Owe 14:12).
B. Kíyèsí pé ìwé Galatia 5:22 bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí “ṣùgbọ́n” Pọ́ọ̀lù Aposteli sọ ìdàkejì àwọn èso ti Ẹ̀mí yìí fún wa.
D. Ẹ jẹ́ kí a wo àwọn ẹsẹ̀ bíbélì yìí (Gal 5:19-21) ṣááju kí á tó dárúkọ àwọn èso wọ̀nyí:
“Ǹ jẹ́ àwọn isẹ́ tí ara farahàn tí ísẹ wọ̀nyí, pansàgà, àgbèrè, ìwà-eri, wọ̀bìà, ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìríra, ìjà, ìlara, ìbínú, asọ̀, ìṣọ̀tẹ̀ adamọ̀, àránkan, ìpànìà, ìmutípara, ìréde-òrun àti irú wọnnì: àwọn ohun tí mo ń wí fún yín tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fun n yín tẹlẹ̀ rí pé, àwọn ohun tí mo ńwí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fun nyin tẹ́lẹ̀ rí pé, àwọn tí ńṣe nǹkan wọnnì kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run”- Gal 5:19-21.
Eléyìí ni àkọsílẹ̀ àwọn ohun tí ẹni tí Ẹ̀mí mímọ́ kò darí rẹ̀ yóò màa ṣe.
Tí o bá jẹ́ onígbàgbọ́, tí ó kò ṣàfihàn èso ti ẹ̀mí nínú ayé rẹ dáradára, ìwọ yóò ní ìrírì wíwá bákan náà- kò ní sí ìdàgbasókè (Jak.2:14-16). Èyí tí ó burú jáì nínú rẹ̀ nipé, àbájáde èsì “èso búburú” ni ikú (Rom.6:20-23, Owe 14:12). Kíyèsí rẹ̀ pé ìwé Galatia 5:22 bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí “Ṣùgbọ́n”. Páùlú Aposteli sọ ìdàkejì èso ti ẹmi yìí fún wa. Ẹjẹ́ kí a wo ẹsẹ̀ tí ó sáájú kí ó tó dárúkọ èso ti ẹ̀mí. “Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ ti ara farahàn ti íṣe ìwọ̀nyí: Panṣágà, àgbèrè, ìwà-eri, wọ̀bìà, ìbọ̀rìsà, oṣó, ìlàrà, ìbínú, asọ̀, ìsọ̀tẹ̀, adamọ̀, àránkan, ìpànìà, ìmutí para, ìréde-òru, àti irú wọnni: àwọn ohun tí mo ńwí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wi fún yin tẹ́lẹ̀ rí pé. Àwọn ti ń ṣe nǹkan báwọnnì kí yóò jogún ìjọba Ọlọ́run” – Gal.5:19-21. Eléyìí ni àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tí ẹni tí a kò tipasẹ̀ Ẹ̀mí darí rẹ̀ yóò máa ní ìṣòrò pẹ̀lú.
IṢẸ́ ṢíṢe KÍLÁÀSÌ KEJÌ: Ǹ jẹ́ Kristẹni tí ó sì ń ṣàfihàn iṣẹ́ ti ara ní ìgbàlà bi?
ÀKOJỌPỌ̀: Ìgbàgbọ́ àwọn onígbàgbọ́ (ẹni náà tí ó kún fún Ẹ̀mí mímọ́) dàbí igi tí ó ní ẹ̀ka tó jẹ́ pé tí a bá tọ́jú rẹ̀ dáradára yóò mú èso jáde ṣùgbọ́n tí a kò bá bìkítà fún un, àtúnbọ̀tán rẹ̀ léwu.
ÌPARÍ:
Lọ́nà kínní, ẹ̀ṣẹ̀ wa máa ńmú èso ìbàjẹ́, májèlé jáde tí o sì máa ń ṣàfihàn ìgbé aye ẹ̀sẹ̀ wa àti tí ó sì máa ń dùn wá níkẹhìn. Lọ́nà kejì, Ẹ̀mí mímọ́ máa ńmú èso tí ó rẹwà, dára, tí o n ṣàfihàn ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run tí yóò sí ṣe ayé wan i rere títí ayéraye.
ÌBÉÈRÈ:
* Kíni ìdí tí Kristẹni fi gbọ́dọ̀ so èso ti ẹ̀mí?
* Kíni ó ń ṣàpèjúwe ìdàkèjì èso ti Ẹ̀mí
ÌYÀNNÀNÁ: Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Kristẹni tí kò ṣàfihàn èso ti Ẹ̀mí mímọ́?
ÀDÚRÀ ÌPARÍ: Baba, jọ̀wọ́ pa gbogbo iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ run tí ó ń dènà mi láti so àwọn èso ti Ẹ̀mi mímọ́.
ISẸ́ ÀMÚRELÉ: Fún wa ní àrídájú márùn ún (5) tí ó ṣàfihàn pé o ní èso ti Ẹ̀mí (Máàkì Mẹ́wàá).

Leave a Reply

Open Heavens Daily Devotional guide was written by Pastor E.A. Adeboye, the General Overseer of the Redeemed Christian Church of God, one of the largest evangelical church in the world and also the President of Christ the Redeemer’s Ministries. The Open Heavens devotional application is available across all mobile platforms and operating systems: iOS, Android, Blackberry, Nokia, Windows Mobile and PC.

Discover more from Open Heavens and RCCG Daily Publications

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading